I. A. Ọba 19:19
I. A. Ọba 19:19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o.
I. A. Ọba 19:19 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Elija bá kúrò níbẹ̀, bí ó ti ń lọ ó bá Eliṣa ọmọ Ṣafati níbi tí ó tí ń fi àjàgà mààlúù mejila kọ ilẹ̀. Àjàgà mààlúù mọkanla wà níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kọ ilẹ̀ lọ. Òun alára wà pẹlu àjàgà mààlúù tí ó kẹ́yìn, ó ń fi í kọ ilẹ̀. Elija kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó gbé e wọ Eliṣa.