I. Sam 11:6-7
I. Sam 11:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ. O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.
I. Sam 11:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi. Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.” Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan.
I. Sam 11:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè. Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLúWA sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.