I. Sam 17:45-47
I. Sam 17:45-47 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn. Lónìí yìí ni OLUWA yóo fà ọ́ lé mi lọ́wọ́, n óo pa ọ́, n óo gé orí rẹ, n óo sì fi òkú àwọn ọmọ ogun Filistini fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ati ẹranko ìgbẹ́. Gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé Ọlọrun wà fún Israẹli. Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”
I. Sam 17:45-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si wi fun Filistini na pe, Iwọ mu idà, ati ọ̀kọ, ati awà tọ̀ mi wá; ṣugbọn emi tọ̀ ọ wá li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti iwọ ti gàn. Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli. Gbogbo ijọ enia yio si mọ̀ daju pe, Oluwa kò fi ida on ọ̀kọ gbà ni la: nitoripe ogun na ti Oluwa ni, yio si fi ọ le wa lọwọ.
I. Sam 17:45-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn. Lónìí yìí ni OLúWA yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli. Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni OLúWA fi ń gbàlà; ogun náà ti OLúWA ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”