I. Sam 19:9-10
I. Sam 19:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru. Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.
I. Sam 19:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tún bà lé Saulu, bí ó ti jókòó ninu ilé rẹ̀ tí ó mú ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, tí Dafidi sì ń lu dùùrù níwájú rẹ̀, Saulu ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi mọ́ ògiri, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà wọ ara ògiri, Dafidi bá sá lọ.
I. Sam 19:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.