I. Tim 1:15-17
I. Tim 1:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki. Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin. Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
I. Tim 1:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìdí tí ó fi ṣàánú mi nìyí, pé èmi ni Kristi Jesu kọ́kọ́ yọ́nú sí ju ẹnikẹ́ni lọ. Mo wá di àpẹẹrẹ gbogbo àwọn tí wọn yóo gbà á gbọ́ tí wọn yóo sì ní ìyè ainipẹkun. Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.
I. Tim 1:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn. Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.