Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

II. Kro 20:17-18YBCV(Bibeli Mimọ)

Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin. Jehoṣafati tẹ ori rẹ̀ ba silẹ: ati gbogbo Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu wolẹ niwaju Oluwa lati sìn Oluwa.

II. Kro 20:17-18BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. ẹ dúró ní ààyè yín; ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà OLúWA tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, OLúWA yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ” Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin OLúWA.

II. Kro 20:17-18YCE(Yoruba Bible)

Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.” Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.