II. Kro 33:12-13
II. Kro 33:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀, O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun.
II. Kro 33:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀. Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun.
II. Kro 33:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀. Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú OLúWA dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé OLúWA ni Ọlọ́run.