II. Kor 12:7-10
II. Kor 12:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja. Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi. On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi. Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara.
II. Kor 12:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga. Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi. Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé. Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.
II. Kor 12:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.