II. Kor 3:7-18
II. Kor 3:7-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ), Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù? Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo. Nitori eyi ti a tilẹ ṣe logo, kò li ogo mọ́ nitori eyi, nipasẹ ogo ti o tayọ. Nitoripe bi eyi ti nkọja lọ ba li ogo, melomelo li eyi ti o duro li ogo. Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ. Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ. Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi. Ṣugbọn titi di oni oloni, nigbakugba ti a ba nkà Mose, iboju na mbẹ li ọkàn wọn. Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro. Njẹ Oluwa li Ẹmí na: nibiti Ẹmí Oluwa ba si wà, nibẹ̀ li omnira gbé wà. Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.
II. Kor 3:7-18 Yoruba Bible (YCE)
Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó? Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó? Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ. Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae? Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní irú ìrètí yìí, a ń fi ìgboyà pupọ sọ̀rọ̀. A kò dàbí Mose tí ó fi aṣọ bojú rẹ̀, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà rí ògo ojú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ògo tíí ṣá ni. Ṣugbọn ọkàn wọn ti le, nítorí títí di ọjọ́ òní, aṣọ náà ni ó ń bo ọkàn wọn nígbà tí wọn bá ń ka ìwé majẹmu àtijọ́. Wọn kò mú aṣọ náà kúrò, nítorí nípasẹ̀ Kristi ni majẹmu àtijọ́ fi di asán. Ṣugbọn títí di ọjọ́ òní, nígbàkúùgbà tí wọn bá ń ka Òfin Mose, aṣọ a máa bo ọkàn wọn. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa Mose, “Nígbàkúùgbà tí ó bá yipada sí Oluwa, a mú aṣọ kúrò lójú.” Ǹjẹ́ Oluwa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Ẹ̀mí Mímọ́. Níbikíbi tí Ẹ̀mí Oluwa bá wà, òmìnira wà níbẹ̀. Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
II. Kor 3:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo! Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ. Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà. Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.