Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

II. A. Ọba 13:21YBCV(Bibeli Mimọ)

O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.

II. A. Ọba 13:21BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

II. A. Ọba 13:21YCE(Yoruba Bible)

Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.