Ṣe àfiwé gbogbo èyà
II. A. Ọba 20:1YBCV(Bibeli Mimọ)
LI ọjọ wọnni ni Hesekiah ṣe aisàn de oju-ikú. Isaiah woli ọmọ Amosi si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́; nitoriti iwọ o kú, iwọ kì yio si yè.
II. A. Ọba 20:1BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.”
II. A. Ọba 20:1YCE(Yoruba Bible)
Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.”