Ṣe àfiwé gbogbo èyà
II. A. Ọba 20:5YBCV(Bibeli Mimọ)
Tun pada, ki o si wi fun Hesekiah olori awọn enia mi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wò ọ sàn: ni ijọ kẹta iwọ o gòke lọ si ile Oluwa.
II. A. Ọba 20:5BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún OLúWA.
II. A. Ọba 20:5YCE(Yoruba Bible)
“Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA