Ṣe àfiwé gbogbo èyà
II. A. Ọba 23:25YBCV(Bibeli Mimọ)
Kò si si ọba kan ṣãju rẹ̀, ti o dabi rẹ̀, ti o yipada si Oluwa tinutinu ati tọkàntọkàn ati pẹlu gbogbo agbara rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo ofin Mose; bẹ̃ni lẹhin rẹ̀, kò si ẹnikan ti o dide ti o dàbi rẹ̀.
II. A. Ọba 23:25BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose.
II. A. Ọba 23:25YCE(Yoruba Bible)
Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose.