Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

II. A. Ọba 7:1YBCV(Bibeli Mimọ)

NIGBANA ni Eliṣa wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Bayi li Oluwa wi, Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyẹ̀fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.

II. A. Ọba 7:1BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Eliṣa wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Èyí ni ohun tí OLúWA sọ, ‘Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun barle kíkúnná kan ní ṣékélì kan àti méjì òsùwọ̀n ọkà barle fún ṣékélì kan ní ẹnu-bodè Samaria.’ ”

II. A. Ọba 7:1YCE(Yoruba Bible)

Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.”