II. Sam 18:9-10
II. Sam 18:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Absalomu si pade awọn iranṣẹ Dafidi. Absalomu si gun ori ibaka kan, ibaka na si gba abẹ ẹka nla igi pọ́nhan kan ti o tobi lọ, ori rẹ̀ si kọ́ igi pọ́nhan na, on si rọ̀ soke li agbedemeji ọrun on ilẹ; ibaka na ti o wà labẹ rẹ̀ si lọ kuro. Ọkunrin kan si ri i, o si wi fun Joabu pe, Wõ, emi ri Absalomu rọ̀ lãrin igi pọ́nhan kan.
II. Sam 18:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.
II. Sam 18:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Absalomu sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Absalomu sì gun orí ìbáaka kan, ìbáaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbáaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò. Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi rí Absalomu so rọ̀ láàrín igi óákù kan.”