Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

II. Sam 23:3-4YBCV(Bibeli Mimọ)

Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun. Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo.

II. Sam 23:3-4BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

II. Sam 23:3-4YCE(Yoruba Bible)

Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’