Iṣe Apo 1:4-5
Iṣe Apo 1:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín. Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.”
Iṣe Apo 1:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi: Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.
Iṣe Apo 1:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”