Iṣe Apo 13:2-3
Iṣe Apo 13:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si. Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ.
Iṣe Apo 13:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ.