Iṣe Apo 28:26-27
Iṣe Apo 28:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wipe, Tọ̀ awọn enia wọnyi lọ, ki o si wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati ni riri ẹnyin ó ri, ẹnyin kì yio si woye: Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada.
Iṣe Apo 28:26-27 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, ‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé: Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín; Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n. Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya, wọ́n ti dijú. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ìbá fi ojú wọn ríran, wọn ìbá fetí gbọ́ràn, òye ìbá yé wọn, wọn ìbá yipada; èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’
Iṣe Apo 28:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.” Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di. Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’