Iṣe Apo 7:57-58
Iṣe Apo 7:57-58 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u, Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu.
Pín
Kà Iṣe Apo 7Iṣe Apo 7:57-58 Yoruba Bible (YCE)
Ni wọ́n bá kígbe, wọ́n fi ọwọ́ di etí, gbogbo wọ́n rọ́ lù ú; wọ́n fà á jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n bá ń sọ ọ́ ní òkúta. Àwọn ẹlẹ́rìí fi ẹ̀wù wọn lélẹ̀ níwájú ọdọmọkunrin kan tí à ń pè ní Saulu.
Pín
Kà Iṣe Apo 7Iṣe Apo 7:57-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
Pín
Kà Iṣe Apo 7