Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Amo 2:4YBCV(Bibeli Mimọ)

Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le.

Amo 2:4BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Èyí ni ohun tí OLúWA wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin OLúWA sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé

Amo 2:4YCE(Yoruba Bible)

Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà.