Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Amo 4:13YBCV(Bibeli Mimọ)

Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Amo 4:13BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Amo 4:13YCE(Yoruba Bible)

Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́, tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan, Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru, tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé; OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!