Kol 4:5-6 - Compare All Versions

Kol 4:5-6 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn.

Kol 4:5-6 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Kol 4:5-6 YCE (Yoruba Bible)

Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ. Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn.