Dan 8:19-21
Dan 8:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, kiyesi i, emi o mu ọ mọ̀ ohun ti yio ṣe ni igba ikẹhin ibinu na: nitoripe, akokò igba ikẹhin ni eyi iṣe. Agbò na ti iwọ ri ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni nwọn. Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.
Dan 8:19-21 Yoruba Bible (YCE)
ó ní, “Ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn ibinu Ọlọrun sí àwọn eniyan lẹ́yìn ọ̀la ni ìran tí o rí. “Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí. Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀.
Dan 8:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn. Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Media àti Persia. Òbúkọ onírun náà ni ọba Giriki, ìwo ńlá ti ó wà láàrín ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.