Dan 8:24-25
Dan 8:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára. Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu.
Dan 8:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Agbara rẹ̀ yio si le gidigidi, ṣugbọn kì iṣe agbara ti on tikararẹ̀: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ́ run. Ati nipa arekereke rẹ̀ yio si mu ki iṣẹ ẹ̀tan ṣe dẽde lọwọ rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga li ọkàn rẹ̀, lojiji ni yio si pa ọ̀pọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade nì; ṣugbọn on o ṣẹ́ laisi ọwọ.
Dan 8:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yóò di alágbára, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́. Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ-aládé, síbẹ̀, a ó pa á run ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.