Dan 9:18-19
Dan 9:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla. Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.
Dan 9:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́. Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.”
Dan 9:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ. OLúWA, fetísílẹ̀! OLúWA, Dáríjì! OLúWA, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”