Deu 6:1-2
Deu 6:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a: Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ.
Deu 6:1-2 Yoruba Bible (YCE)
“Àwọn òfin ati ìlànà, ati ìdájọ́ tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fún mi láti fi kọ yín nìwọ̀nyí; kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà; kí ẹ lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà ati òfin tí mo fun yín lónìí, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ lè pẹ́ láyé.
Deu 6:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí OLúWA Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsi i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jordani. Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀.