Efe 1:18-21
Efe 1:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ, Ati agbara rẹ̀ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ́, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun, Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu.
Efe 1:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ, ati bí agbára rẹ̀ ti tóbi tó fún àwa tí a gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ títóbi agbára rẹ̀. Ó fi agbára yìí hàn ninu Kristi nígbà tí ó jí i dìde ninu òkú, tí ó mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run. Ó ga ju gbogbo àwọn ọlọ́lá ati aláṣẹ ati àwọn alágbára ati àwọn olóye tí wọ́n wà lójú ọ̀run lọ. Ó tún ga ju gbogbo orúkọ tí eniyan lè dá lọ, kì í ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣugbọn ati ní ayé tí ń bọ̀ pẹlu.
Efe 1:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.