Efe 5:21-25
Efe 5:21-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun. Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi fun Oluwa. Nitoripe ọkọ ni iṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi ti ṣe ori ijọ enia rẹ̀: on si ni Olugbala ara. Nitorina gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ̃ si ni ki awọn aya ki o mã ṣe si ọkọ wọn li ohun gbogbo. Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u
Efe 5:21-25 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí Oluwa. Nítorí ọkọ ni olórí aya gẹ́gẹ́ bí Kristi ti jẹ́ olórí ìjọ. Kristi sì ni Olùgbàlà ara rẹ̀ tíí ṣe ìjọ. Bí ìjọ ti ń bọ̀wọ̀ fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.
Efe 5:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.