Est 6:1-2
Est 6:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li oru na ọba kò le sùn, o si paṣẹ pe, ki a mu iwe iranti, ani irohin awọn ọjọ wá, a si kà wọn niwaju ọba. A si ri pe, ati kọ ọ pe, Mordekai ti sọ ti Bigtani, ati Tereṣi, awọn ìwẹfa ọba meji, oluṣọ iloro, awọn ẹniti nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba.
Est 6:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní òru ọjọ́ náà, ọba kò lè sùn. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọba rẹ̀ wá, kí wọ́n sì kà á sí etígbọ̀ọ́ òun. Wọ́n kà á ninu àkọsílẹ̀ pé Modekai tú àṣírí Bigitana ati Tereṣi, àwọn ìwẹ̀fà meji tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba, tí wọ́n dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba.
Est 6:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è sùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kà á sí létí. Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Mordekai tí sọ àṣírí Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n ń gbèrò láti pa ọba Ahaswerusi.