Eks 15:23-25
Eks 15:23-25 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò. Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?” Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn. Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò
Eks 15:23-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara. Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu? O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò
Eks 15:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò). Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?” Mose sì ké pe OLúWA, OLúWA sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni OLúWA ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.