Eks 27:20-21
Eks 27:20-21 Yoruba Bible (YCE)
“Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún títan iná, kí wọ́n lè gbé fìtílà kan kalẹ̀ tí yóo máa wà ní títàn nígbà gbogbo. Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran.
Eks 27:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo. Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.
Eks 27:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀. Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú OLúWA: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.