Eks 7:3-4
Eks 7:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti, síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.
Eks 7:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti.
Eks 7:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ. Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá.