Eks 9:3-4
Eks 9:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọwọ́ OLúWA yóò mú ààrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìbákasẹ, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín. Ṣùgbọ́n OLúWA yóò pààlà sí àárín ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Israẹli àti ti àwọn ara Ejibiti tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Israẹli tí yóò kùú.’ ”
Eks 9:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀. OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli.
Eks 9:3-4 Yoruba Bible (YCE)
àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀. Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli.