Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Esek 12:2YBCV(Bibeli Mimọ)

Ọmọ enia, iwọ ngbe ãrin ọlọ̀tẹ ile, ti nwọn ni oju lati ri, ti kò si ri; nwọn ni eti lati gbọ́, nwọn kò si gbọ́: nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.

Esek 12:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.

Esek 12:2YCE(Yoruba Bible)

“Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.