Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Esek 13:6YBCV(Bibeli Mimọ)

Nwọn ti ri asan ati àfọṣẹ eke, pe, Oluwa wi: bẹ̃ni Oluwa kò rán wọn, nwọn si ti jẹ ki awọn ẹlomiran ni ireti pe, nwọn o fi idí ọ̀rọ wọn mulẹ.

Esek 13:6BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “OLúWA wí,” nígbà tí OLúWA kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí OLúWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.

Esek 13:6YCE(Yoruba Bible)

Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.