Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Esek 15:7YBCV(Bibeli Mimọ)

Emi o si doju mi kọ wọn, nwọn o jade kuro ninu iná kan, iná miran yio si jo wọn, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba dojukọ wọn.

Esek 15:7BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan, síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLúWA.

Esek 15:7YCE(Yoruba Bible)

N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.