Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Esek 38:2-3YBCV(Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Gogu, ilẹ Magogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali, si sọtẹlẹ si i, Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ ọ, iwọ Gogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali
Pín
Esek 38YBCVEsek 38:2-3BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali.
Pín
Esek 38BMYOEsek 38:2-3YCE(Yoruba Bible)
ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Gogu, ní ilẹ̀ Magogu; tí ó jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí, pé OLUWA Ọlọrun ní, Mo lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí Meṣeki ati Tubali.
Pín
Esek 38YCE