Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Esek 7:27YBCV(Bibeli Mimọ)
Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Pín
Esek 7YBCVEsek 7:27BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba yóò ṣọ̀fọ̀, ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí, ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLúWA.’ ”
Pín
Esek 7BMYOEsek 7:27YCE(Yoruba Bible)
Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Pín
Esek 7YCE