Esr 1:2-3
Esr 1:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.
Esr 1:2-3 Yoruba Bible (YCE)
“Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu.
Esr 1:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili OLúWA fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili OLúWA Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu.