Esr 2:68-69
Esr 2:68-69 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀. Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa.
Esr 2:68-69 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA.
Esr 2:68-69 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé OLúWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.