Esr 8:22-23
Esr 8:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe, oju tì mi lati bère ẹgbẹ ọmọ-ogun li ọwọ ọba, ati ẹlẹṣin, lati ṣọ wa nitori awọn ọta li ọ̀na: awa sa ti sọ fun ọba pe, Ọwọ Ọlọrun wa mbẹ lara awọn ti nṣe afẹri rẹ̀ fun rere; ṣugbọn agbara rẹ̀ ati ibinu rẹ̀ mbẹ lara gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ. Bẹ̃li awa gbàwẹ, ti awa si bẹ̀ Ọlọrun wa nitori eyi: on si gbọ́ ẹ̀bẹ wa.
Esr 8:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e. Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa.
Esr 8:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹṣin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbínú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.