Gẹn 1:1-31

Gẹn 1:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta. Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún: Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu. Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ, Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin. Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ. Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn. Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ. Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun. Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.

Gẹn 1:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta. Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu. Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ. Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.” Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn. Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.” Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa.

Gẹn 1:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńláńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹrin. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńláńlá sí inú Òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi Òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ karùn-ún. Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a, akọ àti abo ni Ó dá wọn. Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà: gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.