Gẹn 1:1-9
Gẹn 1:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃.
Gẹn 1:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni. Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Gẹn 1:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.