Gẹn 18:9-15
Gẹn 18:9-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́. O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na. Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin. Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu? OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán? Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan. Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.
Gẹn 18:9-15 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.” Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.” Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn. Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?” OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó? Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.” Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.”
Gẹn 18:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ńkọ́?” Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” Nígbà náà ni OLúWA wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó: Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?” Nígbà náà ni OLúWA wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún OLúWA? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.” Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n OLúWA wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.”