Gẹn 2:1-3
Gẹn 2:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀.
Gẹn 2:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
BẸ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn. Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe.
Gẹn 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.