Gẹn 20:6-7
Gẹn 20:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si wi fun u li ojuran pe, Bẹ̃ni, emi mọ̀ pe li otitọ inu rẹ ni iwọ ṣe eyi; nitorina li emi si ṣe dá ọ duro ki o má ba ṣẹ̀ mi: nitorina li emi kò ṣe jẹ ki iwọ ki o fọwọkàn a. Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ.
Gẹn 20:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.”
Gẹn 20:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.”