Gẹn 27:28-29
Gẹn 27:28-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini: Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ.
Gẹn 27:28-29 Yoruba Bible (YCE)
Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀run ati ilẹ̀ tí ó dára ati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini. Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”
Gẹn 27:28-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun. Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.”