Gẹn 8:1-22

Gẹn 8:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà. Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá. Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati. Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta. Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀ tí ó kàn. Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde. Ẹyẹ yìí bẹ̀rẹ̀ sí fò káàkiri títí tí omi fi gbẹ lórí ilẹ̀. Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde láti lọ wò ó bóyá omi ti gbẹ lórí ilẹ̀, ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé. Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde. Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀. Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́. Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ. Ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù keji ni ilẹ̀ gbẹ tán patapata. Ọlọrun sọ fún Noa pé, “Jáde kúrò ninu ọkọ̀, ìwọ ati aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya wọn. Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.” Noa bá jáde kúrò ninu ọkọ̀, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn aya wọn, pẹlu gbogbo àwọn ẹranko, gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ patapata ni wọ́n bá Noa jáde kúrò ninu ọkọ̀. Noa tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹran ati àwọn ẹyẹ tí wọ́n mọ́, ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ náà. Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí. Níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà, ìgbà gbígbìn ati ìgbà ìkórè kò ní ṣàìwà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà òtútù ati ìgbà ooru, ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yóo sì máa wà pẹlu.”

Gẹn 8:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn. Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. Ní ọjọ́ kẹtà-dínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé. “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.” Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn. Noa sì mọ pẹpẹ fún OLúWA, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. OLúWA sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀: “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà, ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè ìgbà òtútù àti ìgbà ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò, ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru, yóò wà títí láé.”

Gẹn 8:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà. A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá. Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà. Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati. Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn, O si ṣe li opin ogoji ọjọ́, ni Noa ṣí ferese ọkọ̀ ti o kàn: O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ. O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ; Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀. O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ. Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ. O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́. O si ṣe li ọdún kọkanlelẹgbẹta, li oṣù kini, li ọjọ́ kini oṣù na, on li omi gbẹ kuro lori ilẹ: Noa si ṣí ideri ọkọ̀, o si wò, si kiyesi i ori ilẹ gbẹ. Li oṣù keji, ni ijọ́ kẹtadilọgbọ̀n oṣù, on ni ilẹ gbẹ. Ọlọrun si sọ fun Noa pe, Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ. Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ. Noa si jade, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati awọn aya ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; Gbogbo ẹranko, gbogbo ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ gbogbo, ati ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, gẹgẹ bi irú ti wọn, nwọn jade ninu ọkọ̀. Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na. OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe. Niwọ̀n ìgba ti aiye yio wà, ìgba irugbìn, ati ìgba ikore, ìgba otutu ati oru, ìgba ẹ̃run on òjo, ati ọsán ati oru, ki yio dẹkun.