Hag 1:5-6
Hag 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin. Ẹnyin ti fọ́n irugbin pupọ̀, ẹ si mu diẹ wá ile; ẹnyin njẹ, ṣugbọn ẹnyin kò yo: ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ nyin lọrun; ẹnyin mbora, ṣugbọn kò si ẹniti o gboná; ẹniti o si ngbowo ọ̀ya ńgbà a sinu ajadi àpo.
Hag 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín: Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí.
Hag 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”